Uche Mac-Auley | |
---|---|
Ọjọ́ìbí | Uchechukwu Nwaneamaka Delta State, Nigeria |
Ọmọ orílẹ̀-èdè | Nàìjíríà |
Iṣẹ́ | Actress Writer of children story books Movie producer |
Ìgbà iṣẹ́ | 1991-Present |
Notable work | 5th Floor (2017) |
Uche Mac-Auley (tí àbísọ rẹ̀ jẹ́ Uchechukwu Nwaneamaka ) tí a mọ̀ tẹ́lẹ̀ bi Uche Obi Osotule jẹ́ gbajúgbajà òṣèré, ònkọ̀wé, olóòtú sinimá àgbéléwò ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.[1]
Mac-Auley wá láti Ìpínlẹ̀ Dẹ́ltà ní Nàìjíríà. Àwọn òbí Mac-Auley jẹ́ olùkọ́ tí wọ́n sì maá n ṣiṣẹ́ káàkiri. Nítorí ìdí èyí, Mac-Auley kò gbé lójú kan fún ìgbà pípẹ́. Èyí mú kí Mac-Auley lọ sí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ilé-ìwé alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ ṣùgbọ́n ó padà parí ní ilé-ìwé Osoro Primary School, ó sì lọ sí Anglican Girls Grammar School àti Idia College fún ètò-ẹ̀kọ́ girama rẹ̀. Mac-Auley gba oyè-ẹ̀kọ́ nínu ìmọ̀ èdè Gẹ̀ẹ́sì láti ilé-ẹ̀kọ́ gíga Delta state university.[2][3]
A lè ṣàpèjúwe Mac-Auley bi gbajúgbajà òṣèré àti ọ̀kan nínu àwọn ẹni ìṣáájú ní agbo eré sinimá ti Nàìjíríà.[4] Mac-Auley ṣe àkọ́kọ́ ìfihàn rẹ̀ lágbo eré sinimá ti Nàìjíríà pẹ̀lú kíkópa gẹ́gẹ́ bi "Nkemji" nínu eré tẹlifíṣọ̀nù kan ti ọdún 1991 tí a pe àkọ́lé rẹ̀ ní Checkmate, èyítí Amaka Igwe ṣe àgbékalẹ̀ àti dídarí rẹ̀, ní àjọṣepọ̀ pẹ̀lu àwọn òṣèré Nollywood bíi Richard Mofe-Damijo, Norbert Young, Francis Agu, Bimbo Manuel, Kunle Bamtefa, àti Binta Ayo Mogaji. Mac-Auley ní ìsinmi ọlọ́jọ́gbọọrọ nídi iṣẹ́ òṣèré[5][6][7] láti máa kọ ìwé ìtán fún àwọn ọmọdé,[8] ṣùgbọ́n ó padà sí ìdí iṣẹ́ òṣèré ní ọdún 2016 nígbàtí ó kópa nínu fíìmù kan tí àkólé rẹ̀ jẹ́ Mid-Life.[9]
Yàtò sí ṣíṣe iṣẹ́ òṣèré, Mac-Auley tún jẹ́ ònkọ̀tàn àti agbéréjáde, ó sì ti ní lórúkọ rẹ̀, àwọn fíìmù bíi; Dangerous Twins, Sins of my Mother àti In a Lifetime.[10]
Mac-Auley ti ṣe ìgbeyàwó lẹ́ẹ̀mejì ri. Ní àkọ́kọ́ pẹ̀lú olóòtú Obi Osotule, ẹnití ó pàdé ní ọdún 1993 nígbà tí wọ́n fi ń gbaradì fún eré Unforgiven Sin. Mac-Auley padà wá pínyà pẹ̀lú Obi Osotule ní ọdún 2002[11] kí ó tó wá fẹ́ Solomon Mac-Auley ní ọdún 2006.[12]
Orúkọ tí Mac-Auley ń lò tẹ́lẹ̀ nígbà tí Osotule síì jẹ́ ọkọ rẹ̀ ni “Uche Osotule” ṣùgbọ́n lẹ́hìn tí ó fẹ́ ọkọ míràn, ó yí orúkọ rẹ̀ padà sí “Uche Mac-Auley” láti máa jẹ́ orúkọ ọkọ rẹ̀ tuntun.[13]