Titilope Sonuga | |
---|---|
Ọjọ́ìbí | Ilu Èkó |
Ọmọ orílẹ̀-èdè | Nàìjíríà |
Iṣẹ́ | akéwì . enginíà, àti òṣèré |
Titilope Sonuga, ẹni tí àwọn èèyàn mọ sì Titi Sonuga, je akéwì, enginíà, àti òṣèré ni orílẹ̀ èdè Nàìjíríà.[1] Wọ́n bíi sì ìlú Èkó, ó sì lọ sí orílẹ̀ èdè Canada nígbà tí ó pè ọmọ ọdún mẹ́tàlá.[2] Ó siṣẹ́ fún ọdún márùn-ún gẹ́gẹ́ bíi enginíà. Ní ọdún 2011, ó gbà àmì ẹ̀yẹ onkọ̀we tuntun láti ọ̀dọ̀ Canadian Authors Association. Ní ọdún 2012, ó gbé ìgbà orókè níbi ìdíje Maya Angelou Poetry Contest.[3] Ní oṣù karùn-ún ọdún 2015, ó di akéwì àkọ́kọ́ tí ó má farahàn níbi ayẹyẹ tí wọn fi gbé Ààrẹ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà sórí òye. Sonuga tí kéwì níbi ayẹyẹ Lagos International Poetry Festival.[4][5] Yàtọ̀ sí ewì, Sonuga tí kópa nínú eré ṣíṣe. Ó kọ ipa Eki nínú eré Gidi Up pẹ̀lú àwọn òṣèré bíi OC Ukeje, Deyemi Okanlawon, Somkele Iyamah àti Ikechukwu Onunaku.[6] Ó jẹ́ àmbásẹ́dọ̀ fún She Will Connect Program ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà. Ó kọ orin ' 'Ada The Country' '. Ní ọdún 2015, ó ṣe ìkéde ìgbéyàwó rẹ pẹ̀lú ayàwòrán tí orúkọ rẹ̀ jẹ́ Ṣeun Williams.[7][8]