Tina Mba | |
---|---|
Ọjọ́ìbí | 2 October[1] Enugu State |
Orílẹ̀-èdè | Nigeria |
Iṣẹ́ | Actress |
Àwọn ọmọ | 3 |
Tina Mba jẹ́ òṣèré orí-ìtàgé ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tí wọ́n yàn fún àmì-ẹ̀yẹ òṣèrébìnrin tí ó tayọ níbi ayẹyẹ ẹlẹ́keèje ti Africa Movie Academy Awards
Ní ọdún 2017, Tina kópa nínu àwọn eré bíi Isoken, Bariga Suger, Okafor's Law àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ, tí ìwé ìròyìn pulse sì ṣe àpèjúwe rẹ̀ bíi “òṣèrébìnrin tí ó dára jù lọ́dún”. Níbi ayẹyẹ Africa Magic Viewers Choice Awards ti ọdún 2017, wọ́n yàán fún àmì-ẹ̀yẹ òṣèrébìnrin tí ó tayọ jùlọ nínu eré aláwàdà.[2] Ó ṣàlàyé wípé òun kò bá ti fẹ́ràn eré orí ìpele ju sinimá àgbéléwò lọ tóbá ṣe wípé owó rẹ̀ pọ̀ dáada. Ní ọdún 2016, ó kópa nínu eré afìfẹ́hàn kan tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Ufuoma, èyítí Ikechukwu Onyeka darí.[3] Ní Oṣù Kẹẹ̀wá ọdún 2017, ó tún kópa nínu eré Omoye, èyítí ó jẹ́ láti lòdì sí ìfipábánilòpọ̀.[4] Ní ọdún 2017 kan náà ló kópa nínu eré Isoken ní àjọṣepọ̀ pẹ̀lú Fúnkẹ́ Akíndélé àti Dakore Àkàndé. Ó kó ipa ìyá kan tó n fẹ́ kí ọmọ rẹ̀ obìnrin ṣe ìgbeyàwó ní kíákíá.[5]
Ó jẹ́ ọmọ bíbí Ìpínlẹ̀ Ẹnúgu,[6] ó sì ti bí ọmọ méjì.[7]