Thuso Mbedu | |
---|---|
Thuso Mbedu | |
Ọjọ́ìbí | Thuso Nokwanda Mbedu 8 Oṣù Keje 1991 Pietermaritzburg, Kwa-Zulu Natal, South Africa |
Orílẹ̀-èdè | South African |
Ẹ̀kọ́ | Pietermaritzburg Girls' High School |
Iléẹ̀kọ́ gíga | Wits University |
Iṣẹ́ | Actress |
Ìgbà iṣẹ́ | 2014–present |
Thuso Mbendu (bíi ni ọjọ́ kẹjọ oṣù keje ọdún 1991) jẹ́ òṣèré lórílẹ̀ èdè South Áfríkà. Wọn yàán kalẹ̀ fún àmì ẹ̀yẹ Emmy Awards fún ipá tí ó kó nínú eré Is'Thunzi..[1][2][3] Ó kọ ipa Kitso Medupe nínú eré Scandal![4], Nosisa nínú eré Isibaya àti Boni Khumalo nínú eré Saints and Sinners.. [5][6][7]Wọ́n bíi Thuso sì ìlú Pelham ni ilẹ̀ KwasZulu-Natal[8], ibẹ̀ sì ni ó dàgbà sí. Ìyá bàbà rẹ ni ó tọ́jú rẹ títí ó fi dàgbà nítorí pé àwọn òbí rẹ kú nígbà tí ó wà ní ọmọdé. [9]Nígbà tí ó wà ní ọmọ ọdún méjìdínlógún, ó lọ sí ilé ẹ̀kọ́ gíga tí University of WStwatersrand níbi tí ó tí gboyè nínú ìmò Physical Theatre and Performing Arts Management.[10] Ní ọdún 2012, ó lọ sí Stella Adler Studio Acting ni orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà.[11] Ní ọdún 2014, ó kópa ni ránpé nini eré Isibaya kí ó tó wà padà sínu eré Scandal. Thuso bẹ̀rẹ̀ ère orí tẹlẹfíṣọ̀nù nínú eré Is'Thunzi ni oṣù kẹwàá ọdún 2016[12], ó sì kó ipa Winnie nínú eré náà. Ní oṣù kẹsàn-án ọdún 2017[13], wọn yàán fún àmì ẹ̀yẹ tí International Emmy Award fún òṣèré bìnrin to tayọ julọ fún ipá Winnie tí ó kó nínú eré Is'Thunzi.[14]