Teni Aofiyebi | |
---|---|
Ọjọ́ìbí | Teniade Aofiyebi |
Orílẹ̀-èdè | Nigerian |
Iṣẹ́ | Actress, businesswoman |
Teniade Aofiyebi jẹ́ òṣèré[1] àti oníṣòwò[2] lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà.[3] Ó kópa nínú eré Mirror in the Sun ní ọdún 1984 títí di ọdún 1986.[4] Ní ọdún 2003, ó kópa nínú eré For Better, For Worse.[5] Ní ọdún 2005, ó kópa nínú eré Prince of Savannah, èyí tí Bayo Awala ṣe adarí fún.[6] Ní ọdún 2013, ó kópa nínú eré ìfẹ́ Flower Girl, èyí tí Michelle Bello ṣe adarí rẹ̀.[7] Ní ọdún 2015, ó kópa nínú eré Royal Castle tí ó sọ̀rọ̀ nípa ọ̀dalẹ̀, ẹ̀tàn, jìbìtì àti ìfẹ́.[8] Ní oṣù karùn-ún ọdún 2014, Aofiyebi dá ilé iṣẹ́ TKM Essentials kalẹ̀.[9] Ní ọdún 2019, ó ṣe adájọ́ fún ìdíje obìnrin tó rẹwà jùlọ fún àwọn odi.[10] Ó jẹ́ mọ̀lẹ́bí fún Funlola Aofiyebi-Raimi.[11]