Temi Lola Balogun tí orúkọ inagi rẹ̀ jẹ́ TaymiB jẹ́ agbóhùnsáfẹ́fẹ́ ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà. Òun sì ní olùgbé sílẹ̀ ètò Skinny Girl in Transit. Ó lọ sí ilé ẹ̀kọ́ Queen's College ni ìlú Èkó. Ó lọ sí ilé ẹ̀kọ́ gíga tí Nottingham Trent University[1]. Òun àti àbúrò rẹ̀ jọ kọ orin Soyinka's Afro ní ọdún 2009.[2] Balogun di atọ́kun fún ilé iṣẹ́ Cool Fm ni ìlú Èkó.[3] Ó gbé eré Things Men Say jáde ní ọdún 2017.[4][5] Ní ọdún 2019, òun àti N6 jọ ṣe ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nurọ̀ fún olórin Cardi B nígbà tí ó wá sí orílẹ̀ èdè Nàìjíríà[6][7]. Tèmilola jẹ́ ìyàwó fún Timi Akinmuda, wọ́n sì ti bí ọmọ méjì.[8]