Ṣọlá Ṣóbọ̀wálé | |
---|---|
Ọjọ́ìbí | 26 Oṣù Kejìlá 1963 Ìpínlẹ̀ Oǹdó, Nàìjíríà |
Orílẹ̀-èdè | Nàìjíríà |
Ọmọ orílẹ̀-èdè | Nàìjíríà |
Iṣẹ́ |
|
Parent(s) | Joseph Olagookun, Esther Olagookun |
Ṣọlá Ṣóbọ̀wálé tí wọ́n bí ní ọjọ́ kejìdínlógún, oṣù kejìlá, ọdún 1963, jẹ́ òṣèré sinimá àti adarí eré ti orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. [1] Ó di olókìkí ní ọdún 2001, nínú ìṣàfihàn ti Ìtàn-àkọọ́lẹ̀ Super Story : Oh Father, Oh Daughter.
Ó dara pọ̀ mọ́ eré orí ìtàgé nípasẹ̀ ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn fíìmù tí Ẹgbẹ́ Awada Kẹrikẹri ṣe lábẹ́ adarí Adébáyọ̀ Sàlámì . [2] Láàárín ọdún díẹ̀, ó ti ṣe iṣẹ́ akọ̀wé, ìtọ́sọ́nà àti ìgbéjáde ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn fíìmù Nàìjíríà. [3] Ó ṣe akọ̀wé, àgbékalẹ̀ ati ìtọ́sọ́nà, Ohun Oko Somida, fíìmù Nàìjíríà kan tí ó jáde ní ọdún 2010 èyí tí ó ṣe ìràwọ̀ Adébáyọ̀ Sàlámì . [4] Ó ṣe ìfihàn nínú Dangerous Twins, fíìmù ti Nàìjírà tí ó jáde ní ọdún 2004 tí Tádé Ògìdán ṣe, ẹni tó kọ fíìmù yìí ni Níji Àkànní . [5] Ó tún ṣe ìfihàn nínú Family on Fire ìṣelọ́pọ̀ ati ìtọ́sọ́nà nípasẹ̀ Tádé Ògìdán . [6]
Sola Sobowale jẹ́ ìyàwó Dotun Sobowale. Ó bí ọmọ mérin fún ọkọ rẹ̀.[7]
Ní ọdún 2019, ó gba àmì ẹ̀yẹ African Academy Academy (AMAA) fún Òṣèré tó dára jù lọ fún ipá rẹ̀ ní fíìmù King of Boys tó jáde ní ọdún 2018.
|title=
(help)