Sola David-Borha | |
---|---|
David-Borha in 2020 | |
Ọjọ́ìbí | Olusola Adejoke Accra, Ghana |
Orílẹ̀-èdè | Nigerian |
Ẹ̀kọ́ |
|
Iṣẹ́ | CEO of African Regions, Standard Bank |
Board member of | Nigerian Economic Summit Group University of Ibadan Business School Redeemer's University Coca-Cola HBC AG |
Olólùfẹ́ | Married |
Olusola Adejoke David-Borha jẹ́ olùdarí àgbà fún ilé ìfowópámọ́ Standard Bank tí ilẹ̀ Áfríkà láti ọdún 2017.[1][2][3] Ó jẹ́ olùdarí àgbà fún Stanbic IBTC Holdings títí di oṣù kìíní ọdún 2017. Ò jẹ́ adarí fún ẹgbẹ́ Nigerian Economic Summit Group láti ọdún 2015. Ó darapọ̀ mọ́ àwọn adarí IBTC ní oṣù keje ọdún 1994.[4] Ó jẹ́ ìkan láàrin àwọn adarí fún Coca-Cola HBC AG láti ọdún kẹfà ọdún 2015. Ó jẹ́ ìkan láàrin àwọn adarí ní ilé èkọ́ gíga Redeemer's University.[5]
Wọ́n bí David sí ilé Accra ní orílẹ̀ èdè Ghana. Ó padà sí Nàìjíríà nígbà tí ó wà ní ọmọ ọdún mẹ́rìnlá. Ó gboyè jáde láti ilé ẹ̀kọ́ gíga tí University of Ibadan nínú ìmò Economics ní ọdún 1981.[6] O jẹ ọmọ ẹgbẹ́ Chartered Institute of Bankers of Nigeria.[7]
David-Borha bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ní ilé ìfowópámọ́ ti NAL Merchant Bank láti ọdún 1984 títí di ọdún 1989[8] kí ó tó wà darapọ̀ mọ́ ilé ìfowópámọ́ IBTC. Ní ọdún 2007, IBTC ati Stanbic Bank Group parapọ̀ láti di Stanbic IBTC Holdings, Sola sí jẹ̀ ìkan láàrin àwọn olùdarí wọn. Ní oṣù kìíní ọdún 2017, ó gba ipò olùdarí àgbà fún Standard Bank Group.[9] Ó jẹ́ adarí fún CR Services Credit Bereau Plc àti University of Ibadan Business School.[10] Ní ọdún 2016, ó gbà àmì ẹ̀yẹ gẹ́gẹ́ bí oníṣòwò bìnrin fún ilé West Áfríkà àti Áfríkà láti ọ̀dọ̀ All Africa Business Leaders Award.[11] Sola jẹ́ ìyàwó fún David-Borha, wọ́n sì tì bí ọmọ mẹ́ta.[12]