Nneka J. Adams | |
---|---|
Ọjọ́ìbí | Nneka Julie Adams Nigeria |
Orílẹ̀-èdè | Nigerian |
Iṣẹ́ | Actress, film producer, film writer |
Nneka Julie Adams (tí a bí ní 8 Oṣù Kẹẹ̀jọ) tí a mọ̀ ní akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ gẹ́gẹ́ bi Nneka Adams tàbí Nneka J. Adams jẹ́ Òṣèré ọmọ Nàìjíríà tí ó wà ní ìlu Kánádà, ònkọ̀wé fiimu, ó sì n ṣe fiimu. Orúkọ rẹ̀ tan dáada jùlọ fún àwọn ipa rẹ̀ tó kó nínu àwọn fiimu bí Black Men Rock, Flight Last to Abuja àti Nation Under Siege.[1]
Adams dagba ní Ìpínlẹ̀ Èkó, àwọn òbi rẹ̀ síì wá láti Ìpínlẹ̀ Delta, Nàìjíríà. Òun ni èkejì nínu àwọn ọmọ mẹ́fà tí àwọn òbi rẹ̀. Adams lọ sí Ilè-ẹ̀kọ́ gíga Marymount, ó sì lọ sí Yunifásitì ti Ìlú Èkó níbi tí ó ti gba oyè-ẹ̀kọ́ nínu Ìmòye.[2] Ní àkókò tí ó wà ní ilé-ẹ̀kọ́ gíga, ó bẹ̀rẹ̀ àyẹ̀wò fún àwọn ipò iṣẹ́ ní Nollywood,[3] èyí tó sokùn fa ipa àkọ́kọ́ rẹ̀ ní ìgbà tówà lómodún mẹ́tàdínlógún (17).[1]
Ó dá ilé-iṣẹ́ Adams film production sílẹ̀, ilé-iṣẹ́ kan tó n rí sí fiimu, tẹlifíṣọ́nu àti ìpolówó. Lórí ilé-iṣẹ́ naà ni ó ti ṣe fiimu, “Black Men Rock” ni ọdún 2017[4] tó ṣe ìfihàn John Dumel, Ruth Kadiri, Bolanle Ninalowo àti Beverley Osu. Ó tún ṣe fiimu "The Devil in Between"[4] ní èyí tí òun fúnralárarẹ̀, Deyemi Okanlawon àti IK Ogbonna dìjọ kópa nínu rẹ̀.[5] Adams ti hàn nínu àwọn ọ̀pọ̀lọpọ̀ fiimu Nollywood. Lára wọn ni Chronicles of Vendata, Ruth, If You Were Mine, Perfect Combo, A Nation Under Siege àti Last Flight to Abuja.[6]