Nkiru Sylvanus | |
---|---|
Ọjọ́ìbí | Nkiru Sylvanus 21 Oṣù Kẹrin 1982 Ìpínlẹ̀ Abia |
Orílẹ̀-èdè | Nàìjíríà |
Iléẹ̀kọ́ gíga | Enugu State University of Science and Technology |
Iṣẹ́ |
|
Ìgbà iṣẹ́ | 1999-Present |
Nkiru Sylvanus tí wọ́n bí ní ọjọ́ Kọkànlélógún oṣù Kẹ́rin ọdún 1982, jẹ́ òṣèré àti olóṣ̀èlú. Ó tí kópa nínú eré tí ó tó àádójé tí ó sì ti gba àmì-ẹ̀yẹ tí Africa Magic Viewers Choice Awards fún Òṣèré léwájú tí ó peregedé jùlọ nínú ayẹyẹ Africa Movie Academy Awards. [1] [1][2][3][4]
Wọ́n bí Sylvanus ní ìlú Osisioma, ní Ìpínlẹ̀ Abia. Ó lọ sí ilé-ẹ̀kọ́ alákòọ́bẹ̀rẹ̀ ti Ohabiam àti ilé-ẹ̀kọ́ girama ní agbègbè kan náà. Ó sì lọ sí ilé-ẹ̀kọ́ Fásitì gbogbonìṣe ti Ìpínlẹ̀ Enugu tí ó kẹ́kọ́ gboyè nínú ìmọ̀ ìbára-ẹní-sọ̀rọ̀.[5][6][7]
Sylvanus bẹ̀rẹ̀ eré ṣíṣe ní dédé ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún ní ọdún 1999. Ó ti kópa nínú eré tí ó tó àádóje.[1][8][9] Ó ti fara hàn nínú ìwé-ìròyìn The Guardian's ní ọdún 2017 àti 2018 gẹ́gẹ́ bí Gbajúmọ jùlọ lórí ìwé-ìròyìn.[10][11]
Ní ọdún 2011, wọn yàn án Sylvanus sí ara àwọn ìgbìmọ̀ tí Gómìnà Rochas Okorocha gégẹ́ bí olùbádámọ̀ràn sí Ìpìnlẹ̀ Èkó lórí ọ̀rọ̀ àwùjọ.[12][13][14][15]
Wọ́n jí Sylvanus gbé ní ọjọ́ kẹẹ̀dógún oṣù Kejìlá ọdún 2012 tí àwọn ajínigbé náà sì bèrè fún ọgọ́rún mílíọ́nù náírà ( ₦100,000,000) gẹ́gẹ́ bí ìwé-ìròyìn Vanguard tí sọ ṣáájú kí wọ́n tó dá wọn sílẹ̀.[7] [16][17][18][19][20] It was reported by Nigerian media houses that on December 21, 2012 at 10:30pm, Sylvanus was released from her kidnappers.[19]
Ní ọdún 2014, Sylvanus ṣe ìgbéyàwó pẹ̀lú Stanley Duru, àmọ́ wọ́n pín yà ní ọdún 2019. [21][22][23]
|url-status=
ignored (help)
Àdàkọ:Authority Control