Nisha Kalema | |
---|---|
Ọjọ́ìbí | 1993 Kawempe, Kampala, Uganda |
Ọmọ orílẹ̀-èdè | Ugandan |
Ẹ̀kọ́ | Buganda Royal Institute of Business and Technical Education (Certificate in Journalism and Creative Writing) |
Iṣẹ́ | Actress, Producer |
Ìgbà iṣẹ́ | 2014–present |
Awards | Full list |
Nisha Kalema (bíi ni ọdún 1993) jẹ́ òṣèré, akọ́wé àti olùgbé jáde eré lórílẹ̀-èdè Uganda.[1] Ó gbà àmì ẹ̀yẹ gẹ́gẹ́ bí òṣèré bìnrin to dára jù lọ láti ọ̀dọ̀ Uganda Film Festival Award ní ọdún 2015, 2016 àti 2018 fún ipa tí ó kó nínú eré The Tailor, Freedom àti Veronica's Wish.[2]
Kalema di gbajúmọ̀ òṣèré nípa eré Galz About Town. Ó kó ipa olórí àwọn aṣẹ́wó tí orúkọ rẹ̀ jẹ́ Clara nínú eré náà.[3][4] Ní ọdún 2015, Hassan Mageye fi Kalema ṣe Grace nínú eré The Grace. Eré náà sì ló jẹ́ kí ó gbà àmì ẹ̀yẹ òṣèré bìnrin to dára jù lọ tí ó kọ́kọ́ gbà. Ní ọdún 2016, ó gbà àmì ẹ̀yẹ kejì gẹ́gẹ́ bí òṣèré bìnrin to dára jù lọ fún ipa Amelia tí ó kó nínú eré Freedom.[5][6][7] Eré náà sì gba àmì ẹ̀yẹ mẹ́fà. Ní ọdún 2016, ó ṣe Prossy nínú eré Jinxed. Ní ọdún 2018, ó kó ipa Veronica nínú eré Veronica's Wish. Ó ṣe bí èèyàn tó ní àrùn jẹjẹrẹ nínú eré náà.[8] Eré náà sì ló jẹ́ kí ó gbà àmì ẹ̀yẹ kẹta gẹ́gẹ́ bí òṣèré bìnrin to dára jù lọ. Eré náà sì ti gba àmì ẹ̀yẹ mẹ́ẹ̀sán.[9]
Kalema lọ sí ilé ẹ̀kọ́ St Charles Lwanga Primary School àti Kainabiri Secondary. Ó gboyè nínú ìmò ìròyìn láti ilé ẹ̀kọ́ gíga tí Buganda Royal Institute of Business and Technical Education ní ọdún 2013.[10]
Ọdún | Àkọ́lé | Ipa tí ó kó |
---|---|---|
2014 | Hanged For Love | Jackie |
Galz About Town | Clara | |
2015 | The Tailor | Grace |
2016 | Freedom | Amelia |
The Only Son | Diana | |
Ugandan Pollock | Lee Krassner | |
Jinxed | Prossy | |
2018 | Veronica's Wish | Veronica |
Ọdún | Àkọ́lé |
---|---|
2014 | It Can’t Be |
2016 | Yat Madit |
Ọdún | Àkọ́lé | Ipa tí ó kó |
---|---|---|
2017 | Freedom | Amelia |
Year | Nominated work | Association | Category | Esi | Ref. |
---|---|---|---|---|---|
2015 | The Tailor | Uganda Film Festival Awards | Best Actress | Gbàá | [11] |
2016 | Freedom | Gbàá | [12][13] | ||
2018 | Veronica's Wish | Gbàá | [14] | ||
Best Script (Screen Play) | Gbàá | ||||
Best Feature Film | Gbàá | ||||
2019 | Mashariki African Film Festival | Best East African Feature Film | Yàán | [15] |