Nicole Amarteifio | |
---|---|
Ọjọ́ìbí | 1982 (ọmọ ọdún 41–42) |
Orílẹ̀-èdè | Ghanaian |
Iléẹ̀kọ́ gíga | Brandeis University Georgetown University |
Iṣẹ́ | Film director, producer, screenwriter |
Ìgbà iṣẹ́ | 2012–present |
Nicole Amarteifio (tí a bí ní ọdún 1982) jẹ́ agbéréjáde, olùdarí àti ònkọ̀tàn eré ọmọ orílẹ̀-èdè Ghánà.
A bí Amarteifio ní orílẹ̀-èdè Ghánà ṣùgbọ́n ó gbé ní Ìlú Lọ́ndọ̀nù fún ọdún mẹ́fà láti ìgbà tí ó fi wà lọ́mọ oṣù mẹ́ta nítorí ìfipágbàjọba tí ó ṣẹlẹ̀ ní orílẹ̀-èdè rẹ̀.[1] Ó padà tún kúrò ní ìlú Lọ́ndọ̀nù pẹ̀lú ẹbí rẹ̀ láti lọ gbé ní agbègbè Scarsdale ní ìlú New York, ṣùgbọ́n ó maá n lọ sí orílẹ̀-èdè Ghánà lọ́dọọdún láti lo àwọn àsìkò ìsinmi rẹ̀.[2] Àwọn òbí Amarteifio padà sí orílẹ̀-èdè Ghánà ní ọdún 1997. Ó gba oyè-ẹ̀kọ́ nínu ìmọ̀ nípa àwọn ẹ̀yà aláwọ̀dúdú láti ilé-ẹ̀kọ́ gíga Brandeis University ní ọdún 2004.[3] Lẹ́hìn ìparí ẹ̀kọ́, ó rí iṣẹ́ sí ilé-iṣé Whitaker Group, èyí tí ó wà ní Washington,DC gẹ́gẹ́ bi alámọ̀ràn fún ìdàgbàsókè ètò ọrọ̀-ajé Áfíríkà.[4]
Ní ọdún 2006, Amarteifio lọ sí Accra, orílẹ̀-èdè Ghana láti ṣiṣẹ́ ìdàgbàsókè ọrọ̀-ajé. Láìpẹ́jọjọ sí ìgbà náà, ó ní ìròrí láti ṣe ìbádógba eré Sex and the City ní ìlú Accra.[5] Amarteifio padà sí orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà láti lọ kẹ́kọ̀ọ́ ìmọ̀ ìbaráẹnisọ̀rọ̀ ní ilé-ẹ̀kọ́ gíga Georgetown University ó sì gba oyè-ẹ̀kọ́ gíga ní ọdún 2010.[1] Nígbà tí ó fi wà ní ìlú Georgetown, ó kẹ́kọ̀ọ́ lábẹ Mike Long, ẹnití ó gbàá níyànjú láti máa ṣiṣẹ́ ìfẹ́ ọkàn rẹ̀ gẹ́gẹ́ bi ònkọ̀tàn eré.[6] Amarteifio gba iṣẹ́ ilé ìfowópamọ́ àgbáyé, èyí tí ó mú kí ó padà sí ìlú Accra. Lẹ́hìn oṣù mélòó kan tí ó padà sí Ghánà, ó bẹ̀rẹ̀ sí ní fi ìròrí eré rẹ̀ tó àwọn òṣìṣé eré tẹlifíṣọ̀nù létí. Wọ́n kọ̀ láti gba iṣẹ́ náà ṣùgbọ́n wọ́n gbàá níyànjú láti kọ́ bí a ṣé n kọ ìwé eré.[7]