Moyo Lawal | |
---|---|
Ọjọ́ìbí | January 1 Badagry, Lagos State |
Ọmọ orílẹ̀-èdè | Nàìjíríà |
Iléẹ̀kọ́ gíga | University of Lagos |
Iṣẹ́ | Actress |
Notable work | Holding Hope |
Moyọ̀ Lawal jẹ́ òṣèré ni orílẹ̀ èdè Nàìjíríà[1][2][3][4][5]. Ó gbà àmì ẹ̀yẹ Revelation of the Year láti ọ̀dọ̀ Nollywood Awards ní ọdún 2012.[6]
Wọ́n bí Lawal sí ìlú Badagry. Ó gboyè nínú ìmò Creative arts láti ilé ẹ̀kọ́ gíga tí Yunifásítì ìlú Èkó.[7][8]
Ó kópa nínú ìdíje Next Movie Star àmọ́ kò yege níbẹ̀.[9] Ó bẹ̀rẹ̀ eré ṣíṣe nínú eré Shallow Waters, ó sì kó ipa Chioma nínú eré náà. Lawal di gbajúmọ̀ nígbà tí ó kó ipa Chinny nínú eré Tinsel. [10] Ní ọdún 2012, ó gbà àmì ẹ̀yẹ Revelation of the Year láti ọ̀dọ̀ BON Awards.[11]