Monicazation | |
---|---|
Orúkọ àbísọ | Monica Omorodion Swaida |
Ìbẹ̀rẹ̀ | Edo, Nigeria |
Irú orin | |
Occupation(s) | Singer, songwriter |
Instruments | Vocals |
Years active | 2007 –present |
Associated acts |
Monica Omorodion Swaida (tí ọjọ́ ìbí rẹ̀ jẹ́ 5 Oṣù Kaàrún) tí a mọ̀ sí Monicazation jẹ́ òṣèrébìnrin, akọrin, àti olùgbéréjáde ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà àti Amẹ́ríkà. Ó tún jẹ́ òṣìṣẹ́ ilé-iṣẹ́ Máàdámidófò kan.[1][2]
Ilẹ̀gẹ̀ẹ́sì ni wọ́n bí Swaida sí ṣùgbọ́n ó dàgbà ní ìlú Warri, orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Ó lọ sí ilé-ìwé alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ Nana Primary School ní ìlú Warri, àti ilé-ìwé girama Mount Wachusett Community College ní ìlú Massachusetts .[citation needed]
Ní àkókò tí ó wà ní ilé-ẹ̀kọ́ gíga University of Massachusetts Lowell, Monica jẹ́ asíwájú àwọn ẹgbẹ́ oníjó ní ilé-ẹ̀kọ́ náà. Ó ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn eré ijó, ó sì tún kọ ewì fún ẹgbẹ́ eré orí-ìtàgé nígbà náà.[3] Ó maá n tẹ́tí sí orin Majek Fashek, ẹnití ó pè ní àwòkọ́ṣe rẹ̀.[4]
Omrorodion bẹ̀rẹ̀ sí ní kọrin láti ọmọ ọdún mẹ́rìnlá.[5] Ó pàdé àwọn ọ̀pọ̀lọpọ̀ òṣìṣẹ́ akọrin bíi Sam Morris àti Majek Fashek, ó sì maá n lọ sí ilé-ìṣeré fún ìdánilẹ́kọ̀ọ́. Ó maá n tẹ̀lé Majek Fashek káàkiri lọ síbi àwọn iṣẹ́ orin rẹ̀. Monicazation ṣe àgbéjáde àkójọ àwọn orin rẹ̀ tí ó pe àkólé rẹ̀ ní Monicazation ní Oṣù Kẹẹ̀sán Ọdún 2014.[6]
Omorodion ti kópa nínu ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn fíìmù gígùn tó fi mọ́ Affairs of the Heart ní àjọṣepọ̀ pẹ̀lú Joseph Benjamin àti Stella Damasus ní ọdún 2014. Ní ọdún kan náà, ó tún kópa nínu eré Burning Love, èyí tí Obed Joe kọ ìtàn rẹ̀. Ó tún ti gbé eré tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Faces of Love jáde, èyí tí ó padà gba àmì-ẹ̀yẹ.[7]
|url-status=
ignored (help)