Mercy Eke | |
---|---|
Eke ní ọdún 2019 | |
Ọjọ́ìbí | Imo State, Nigeria |
Ẹ̀kọ́ | Imo State University |
Iṣẹ́ |
|
Ìgbà iṣẹ́ | 2019–present |
Television | Big Brother Naija |
Mercy Èké jẹ́ òṣèré, oníjó àti oníṣòwò lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Ó gbé ìgbà orókè níbi ìdíje Big Brother Naija tí apá kẹrin tí wọ́n ṣe ní oṣù kẹwàá ọdún 2019. Òhun ní obìnrin àkọ́kọ́ tí ó má kọ́kọ́ dé ipò náà.[1][2] Ní ọjọ́ kẹrìnlá oṣù kẹta ọdún 2020, ó gbà àmì ẹ̀yẹ obìnrin tó múra tí ó dára jù lọ níbi ayẹyẹ Africa Magic Viewer's Choice Award.[3]
Eke jẹ́ ọmọ Ìpínlẹ̀ Ímò. Ó lọ sí ilé ẹ̀kọ́ Egbu Girls Secondary School ní ìlú Owerri. Ó gboyè jáde láti ilé ẹ̀kọ́ gíga tí Imo State University ní ọdún 2014.
Eke darapọ̀ mọ́ ìdíje Big Brother Naija ní ọjọ́ ọgbọ̀n oṣù kẹfà ọdún 2019. Ó gbé ìgbà orókè ní oṣù kẹwàá ní ọdún náà[4]. Ní ọdún 2020, ó farahàn nínú eré Alakada, èyí sì ni eré tí ó má kọ́kọ́ ṣe.[5] Ó farahàn gẹ́gẹ́ bí oníjó nínú eré orin Baby Mama èyí tí Davido àti Ichaba gbé kalẹ.[6] Ó tún jó nínú orin Nawo Nawo èyí tí Airboy kọ.[7] Eke jẹ́ àmbásẹ́dọ̀ fún Ciroc àti Mr Taxi.[8][9]
Ọdún | Ayẹyẹ | Category |
---|---|---|
2019 | Scream Awards | Celebrity Sensation of the year[10] |
2020 | AMVCA | Best Dressed female[11] |
2020 | Net Honours | Most Popular Couple[12] |