Mary Njoku | |
---|---|
Ọjọ́ìbí | 20 Oṣù Kẹta 1985 Lagos, Nigeria |
Orílẹ̀-èdè | Nigerian |
Iṣẹ́ |
|
Ìgbà iṣẹ́ | 2003-present |
Olólùfẹ́ | Jason Njoku (married 2012) |
Àwọn ọmọ | 3 |
Mary Nnena Njoku (bí ní ọjọ́ ogún, oṣù kẹta ọdún 1985) jẹ́ òṣèré àti adarí fún ilé iṣẹ́ ROK Studios ni orílẹ̀ èdè Nàìjíríà.[1] Óun ni ó gbé eré Thy Will be Done àti Husband of Lagos jáde, ó sì ṣe adarí fún eré Single Ladies àti Festac Town.
Mary Njoku jẹ́ ọmọ kẹfà nínú àwọn ọmọ mẹ́jo tí àwọn òbí rẹ bí. Wọ́n bí sí ìlú Amuwo Odofin ní Ìpínlẹ̀ Èkó. Ó jẹ́ ọmọ Nsukka ní Ìpínlẹ̀ Ẹnúgu.[2] Ó lọ sí ilé ẹ̀kọ́ Amuwo Odofin High School. Ó lọ sí ilé ẹ̀kọ́ gíga tí Lagos State University níbi tí ó tí gboyè nínú ìmò èdè gẹ̀ẹ́sì. Njoku darapọ̀ mọ́ Nollywood ní ọdún 2003, nígbà tí ó wà ní ọmọ ọdún mẹ́tadínlógún [3].
Njoku kópa nínú eré Home Sickness ní ọdún 2004, èyí sì ni eré tí ó má kọ́kọ́ ṣe. Ó di gbajúmọ̀ lẹ́yìn tí ó kópa nínú eré Blackberry Babes ní ọdún 2011.[4] Láàrin ọdún 2011 àti 2013, ó dá iRoktv kalẹ̀. Ní ọdún 2018, ó gbé eré rẹ̀ kalẹ̀ tí ó pè ní Nwanyioma.[5]
Mary Njoku ṣe ìgbéyàwó pẹ̀lú Jason Njoku ní ọjọ́ kẹjidínlógún oṣù kẹjọ ọdún 2012. Ó ti bí ọmọ mẹ́ta.[6]