Manon Bresch | |
---|---|
Bresch in 2016 | |
Ọjọ́ìbí | 4 Oṣù Kínní 1994 Paris |
Orílẹ̀-èdè | French-Cameroonian |
Iṣẹ́ | Actress |
Ìgbà iṣẹ́ | 2012-present |
Manon Bresch (tí wọ́n bí ní 4 Oṣù Kínní, Ọdún 1994) jẹ́ òṣèrébìnrun ọmọ orílẹ̀-èdè Fráǹsì àti Kamẹrúùnù.
Bresch kọ́ ẹ̀kọ́ eré-ìtàgé ní ilé-ìwé Cours Florent, tí ó wà ní ìlú Paris fún ọdún méjìlá gbáko.[1] Ó ní ìbátan pẹ̀lú orílẹ̀-èdè Kamẹrúùnù tí ó sì ti ṣàbẹ̀wò síbẹ̀ fún àwọn àkókó ìsimi rẹ̀.[2] Bresch kó àkọ́kọ́ ipa fíìmù rẹ̀ ní ọdún 2012 nínu Les Papas du dimanche.[3]
Bresch darapọ̀ mọ́ àwọn olùkópa eré tẹlifíṣọ̀nù tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Clem ní ọdún 2015, níbi tí ó ti kópa gẹ́gẹ́ bi Yasmine, ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ Salomé.[4] Ní Oṣù Kẹẹ̀sán Ọdún 2015, Bresch kópa gẹ́gẹ́ bi Thérèse Marci, ọmọbìnrin kan tí Thomas àti Gabriel gbà tọ̀ọ́, nínu eré tẹlifíṣọ̀nù tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Plus belle la vie. Tia Diagne ni òṣèrébìnrin tí ó kó ipa náà tẹ́lẹ̀ tí ó sì fi sílẹ̀ láti lépa àwọn ànfàní míràn.[5] Ní ọdún 2017, Bresch kó ipa Charlotte Castillon,nínu eré tẹlifíṣọ̀nù Noir enigma.[6][7] Bresch tún kó ipa Luisa gẹ́gẹ́ bi ọmọ akẹ́kọ̀ọ́ kan tí ó ní àwọn agbára idán, nínu eré tẹlifíṣọ̀nù ti ọdún 2019 kan tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Mortel.[8] Ní ọdún 2020, ó kó ipa Sirley gẹ́gẹ́ bi ọmọ akẹ́kọ̀ọ́ oníjọ̀gbọ̀n kan nínu eré Maledetta primavera.[9]
Yàtọ̀ sí èdè Faransé, Bresch tún maá n sọ èdè Gẹ̀ẹ́sì àti èdè Spéìn níwọ̀nba. Ó maá ṣe eré júdò, tẹníìsì, àti ijó ìgbàlódé.[10]