Mabel Akomu Oboh | |
---|---|
Ọjọ́ìbí | 18 Oṣù Kẹrin 1964 Edo State, Nigeria |
Iṣẹ́ | Broadcaster, Journalist, Actress, Producer, Director |
Olólùfẹ́ | Michael Ini Udoh |
Mabel Akomu Oboh tí a mọ̀ sí Mabel Oboh tí wọ́n bí ní 18 Oṣù Kẹẹ̀rin, Ọdún 1964 jẹ́ òṣèrébìnnrin, atọ́kùn ètò orí tẹlifíṣọ̀nù àti agbéréjáde ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Òun ni olùdásílẹ̀ Mabel Oboh Centre for Save our Stars (MOCSOS). Ó jẹ́ àkọ́kọ́ ẹni tí yóó dánìkan gbé eré tẹlifíṣọ̀nù jáde pẹ̀lú eré rẹ̀ tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Victims, tí ó jẹ́ gbígbé jáde lóri ìkànnì Nigerian Television Authority (NTA).[1][2][3][4][5][6]
Mabel wá láti Ìpínlẹ̀ Ẹdó ṣùgbọ́n ìlú Èkó ni àwọn òbí rẹ̀ bi sí. Ó gboyè ẹ̀kọ́ nínu ìmọ̀ nípa òràn dídá láti ilé-ẹ̀kọ́ gíga Buckinghamshire New University.
Mabel bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òṣèré rẹ̀ lágbo eré ìdárayá ní ìbẹ̀rẹ̀ àwọn ọdún 1980. Ó jẹ́ ẹ̀kejì obìnrin tí yóó kọ́kọ́ dánìkan ṣe adarí eré àti olùgbéréjáde pẹ̀lú ṣíṣe eré rẹ̀ tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Victims. Ní ọdún 2000, ó jẹ́ obìnrin àkọ́kọ́ tí. yóó gbàlejò lóri ètò tẹlifiṣọ̀nù pẹ̀lú ètọ̀ tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ "Chat with Mabel" tí wọ́n gbé sáfẹ́fẹ́ lóri ìkànnì NTA.[7][8][9][10]
Ó darapọ̀ mọ́ ilé-iṣẹ́ NTA ní àwọn ọdún 1990 gẹ́gẹ́ bi olùgbéròyìn ṣááju kí ó tó ṣiṣẹ́ pẹ̀lú Aajọ Agbaye. Lẹ́hìn náà ni ó darapọ̀ mọ́ ilé-iṣẹ́ aṣojú Britani ní orílẹ̀-èdè Pólàndì.[11][12]
Lọ́wọ́lọ́wọ́, Mabel jẹ́ alágbàsọ fún ẹgbẹ́ òṣèlú African Democratic Congress (ADC).[13][14][15][16]
Ó gbégbá ìbò ní ọdún 2020 fún ti ètò ìdìbò Gómìnà Ìpínlẹ̀ Ẹdó.
Ó jẹ́ olùdásílẹ̀ Mabel Oboh Centre for Save our Stars (MOCSOS), léte láti ṣe ìrànlọ́wọ́ fún ìlera àwọn òṣèré Nàìjíríà.[17][18][19][20]
Ó ti bí àwọn ọmọkùnrin mẹ́ta, orúkọ ọkọ rẹ̀ náà sì ń ṣe Michael Ini Udoh.[21]