Latefa Ahrar | |
---|---|
Ọjọ́ìbí | 12 Oṣù Kọkànlá 1971 Meknes |
Orílẹ̀-èdè | Moroccan |
Iṣẹ́ | Actress |
Ìgbà iṣẹ́ | 2006-present |
Latefa Ahrar (tí a bí ní 12 Oṣù Kọkànlá Ọdún 1971) jẹ́ òṣèrébìnrin ọmọ orílẹ̀-èdè Mòrókò.
A bí Ahrar ní ìlú Meknes. Ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ eré tẹlifíṣọ̀nù rẹ̀ pẹ̀lú kíkópa nínu eré Bent Lafchouch látọwọ́ Abdelatif Ayachi ní ọdún 1990.[1] Lẹ́hìn náà, ó lọ ilé-ẹ̀kọ́ Institut supérieur d ›art dramatique et d’animation culturelle (ISADAC) níbití ó ti gboyè ní ọdún 1995.[2] Láti ìgbà náà, ó ti ṣe àwọn eré ìpele àti sinimá àgbéléwò, ó sì ti gba ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn àmì-ẹ̀yẹ fún àwọn iṣẹ́ takuntakun rẹ̀. Ahrar ṣàlàyé pé òun fẹ́ràn láti máa kó àwọn ipa tí ó nì ìpèníjà, bẹ́ẹ̀ lòún sì gbádùn láti máa ṣiṣẹ́ pọ̀ pẹ̀lú oríṣiríṣi àwọn olùdarí eré láti mú ìdàgbàsókè bá iṣẹ́ òṣèré rè.[3]
Láti ọdún 2005 sí 2008, Ahrar kópa nínu eré La dernière nuit tí ààjọ Institut du monde arabe gbé kalẹ̀ ní ìlú Paris. Ní ọdún 2008, ó kópa nínu fíìmù méjì kan tí àkọ́lé wọn ń ṣe Une famille empruntée àti Les victimes. Nínu fíìmù àkọ́kọ́, ó kó ipa apanilẹ́ẹ̀rín kan gẹ́gẹ́ bi ọ̀rẹ́bìnrin Mouna Fettou, ṣùgbọ́n gẹ̀gẹ̀ bi ìyàwóolé tí ó ní àwọn ọmọ mẹ́ta nínu fíìmù ẹ̀kejì.[4]
Ní ọdún 2009, ó kópa nínu eré Eduardo De Filippo kan tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Douleur sous clé, èyítí wọ́n túmò sí èdè Mòrókò, pẹ̀lú àjọṣepọ̀ Hicham Ibrahimi àti Henri Thomas. Atúmọ̀ èdè náà jẹ́ Abdellatif Firdaous tí olùdarí sì jẹ́ Karim Troussi.[5]
Eré rẹ̀ kan tí àkọ́lé rẹ̀ n ṣe “Kafar Naoum” fa àríyànjiyàn nítorí wíwọ ṣòkòtò pénpé rẹ̀ nínu eré náà, èyítí ó mú kí àwọn ẹnìkan dérùbàá pẹ̀lú ìjìyà ikú. Á tún mọ Ahrar gẹ́gẹ́ bi ọ̀jọ̀gbọ́n nínu ìmọ̀ eré ìtàgé.[6]