Jumoke George | |
---|---|
Ọjọ́ìbí | Olajumoke Amoke Olatunde George 18 February |
Ọmọ orílẹ̀-èdè | Nàìjíríà |
Iṣẹ́ | actress, movie producer, filmmaker |
Notable work | The Wedding Party |
Jùmọ̀kẹ́ George tí orúkọ àbísọ rẹ̀ n ṣe Ọlájùmọ̀kẹ́ Àmọ̀kẹ́ Ọlátúndé George jẹ́ òṣèrébìnrin àti olùgbéré-jáde ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Ó ti wà nídi iṣẹ́ òṣèré fún ìgbà tí ó ti lé ní ogójì ọdún, tó sì ti kópa nínu ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn eré Nollywood lédè Yorùbá àti Gẹ̀ẹ́sì.
Wọ́n bí Jùmọ̀kẹ́ George ní Ọjọ́ 18 Oṣù Kejì. Òṣìṣẹ́ ológun ni àwọn òbí rẹ̀. Àwọn ilé-ìwé tí ó lọ ní Command Children School tí ó wà ní Yaba ní ìlú Èkó; Army Children School Kánò; Anglican Grammar School, Oríta mẹ́fà, Ìbàdàn àti Government Technical Colllege, Òṣogbo. Àwọn òbí rẹ̀ pínyà nígbà tí ó sì wà lọ́mọdé.[1]
Jùmọ̀kẹ́ George bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òṣèré nígbà tí ó wà lọ́mọ ọdún mẹ́jọ. Nígbà náà, ó kópa nínu eré orí ìpele kan tí ilé-iṣẹ́ ìkànnì National Television Authority (NTA) gbé kalẹ̀ ní ìlú ìbàdàn. Ó forúkọsílẹ̀ nínu ẹgbẹ́ òṣèré NTA ti ìlú ìbàdàn. Ó wọ agbo òṣèré Nollywood nípasẹ̀ Comrade Victor Ashaolu, ẹni tí ó ṣiṣẹ́ lábẹ rẹ̀ fún bi ọdún mọ́kànlá. Ní àwọn ìgba kan, Jùmọ̀kẹ́ kọ̀ láti rí àwọn ipa eré. Láàrin àwọn àsìkò náà ni ó darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ Freelance and Independent Broadcasters Association of Nigeria.(FIBAN) Níbẹ̀ ló ti wá n ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bi atọ́kùn ètò tí ó sì n ṣe atọ́kùn àwọn ètò tí ó lé ní mẹ́rin.[2]
City People Movie Matriarch Recognition Award 2018[5]