Gertrude Webster Kamkwatira jẹ́ òṣèré àti olùdarí eré lórílẹ̀-èdè Malawi. Wọ́n bí Kamkwatira ní ọdún 1966. Ó di adarí fún Wakhumbata Ensemble Theatre ní ọdún 1999 lẹ́hìn ikú olùdásílẹ̀ rẹ̀.[1] Lẹ́hìn ìgbà tí ó fi ẹgbẹ́ náà sílẹ̀, ó ẹgbẹ́ Wanna-Do kalẹ̀.[2] Òun ni Ààrẹ fún National Theater Association ti Malawi àti alága fún Copyright Society ní Malawi.[3] Kamkwatira kọ eré mẹ́tàlá[4] ni èdè gẹ̀ẹ́sì, lára àwọn eré náà ni It's My Fault[5], Jesus Retrial àti Breaking the News.[6][7][8] Ó kú ní ọdún 2006 nípa àrùn ìbà.[9]