Cossy Orjiakor | |
---|---|
Ọjọ́ìbí | October 16 Anambra State |
Ọmọ orílẹ̀-èdè | Nàìjíríà |
Iléẹ̀kọ́ gíga | University of Nigeria Lagos State University |
Iṣẹ́ | actress, singer, video vixen |
Ìgbà iṣẹ́ | 2012 - present (acting career) |
Notable work | Papa Ajasco |
Cossy Orjiakor (tí a bí ní 16 Oṣù Kẹẹ̀wá) jẹ́ òṣèré orí-ìtàgé ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, olùgbéréjáde, akọrin, àti oníjó. Ó di gbajúmọ̀ lẹ́hìn tí ó hàn nínu fídíò orin kan tí Obesere ṣe.[1] Àwọn awuye sì tún wà lóri pé ó maá n fí ọmú rẹ̀ hàn síta tí ó bá wà láàrin àwùjọ àti nígbà tí ó bá n ṣiṣẹ́ ijó rẹ̀ nínu fídíò orin.[2] Ní ọdún 2015, ó ṣe àkọ́kọ́ àgbéjáde fíìmù rẹ̀ tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Power girls, láti ilé-iṣẹ́ rẹ̀ táa pè ní Playgirl pictures.[3]
A bí Orjiakor ní Ìpínlẹ̀ Anámbra.[4][5] Ó parí ilé-ìwé gíga pẹ̀lú gbígba oyè nínu ìmọ̀ ìṣirò àti ìṣàkóso láti Yunifásítì ilẹ̀ Nàìjíríà ti ìlú Nsukka, ó sì padà tún gba oyè gíga láti Ilé-ẹ̀kọ́ gíga Yunifásítì Ìpínlẹ̀ Èkó.[6][7]
Orjiakor jẹ́ ẹni tí àwọn èyàn mọ̀ fún fífi ọmú rẹ̀ hàn síta láàrin àwùjọ. Ó ṣe àpèjúwe ọmú rẹ̀ gẹ́gẹ́ bi ore ńlá láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, ó sì sọ́ di mímọ̀ wípé òun kì yóò fún àwọn ọmọ òun lọ́mú bí alárà.[8] Awuyewuye sì tún wà lóri pé ṣíṣí igbá àyà rẹ̀ síta lékún n tó fi tètè di ìlúmọ̀ọ́ká.[9] Ìwé ìròyìn Daily Post àti Vanguard ṣe àpéjúwe rẹ̀ bi òṣèré onirawọ ọmu ti Nollywood.[10][11] Nínu ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò kan pẹ̀lú Ìwé ìròyìn Encomium, ó ṣàlàyé wípé ṣíṣe ìyá àwọn ọmọ òun mú lẹ̀mí òun ju níní ọkọ lọ.[12]
Orjiakor ti ṣiṣẹ́ ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ oríṣiríṣi eré ìdárayá.[13] Ó ti ṣe ìfihàn nínu àwọn fídíò orin àti fíìmù, ó sì ti kọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ orin.Ó ṣe àgbéjáde àkọ́kọ̀ àkójọpọ̀ àwon orin rẹ̀ tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Nutty Queen ní ọdún 2013, èyítí ó ṣàlàyé wípé ó ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀kọ́ pàtàkì nínú.[14] Ó sọ di mímọ̀ wípé òun kò dédé máa ṣí ara òun sílẹ̀ lásán bí kò ṣe pé láti máa fi ṣe ìpolówó ara rẹ̀ ní agbo eré ìdárayá.[15]
|url-status=
ignored (help)
|url-status=
ignored (help)
|url-status=
ignored (help)
|url-status=
ignored (help)