Clarion Chukwura-Abiola | |
---|---|
Ọjọ́ìbí | Clara Nneka Oluwatoyin Folashade Chukwurah 24 July 1964 (ọmọ ọdún 59) Ilu Eko, Naijiria |
Iṣẹ́ | Osere itage |
Ìgbà iṣẹ́ | 1979–iwoyi |
Àwọn ọmọ | Clarence Peters |
Chief Clarion Chukwura (tí orúkọ ìbí rẹ̀ jẹ́ Clara Nneka Olúwatóyìn Foláshadé Chukwurah; 24 Oṣù Keèje ọdún 1964) jẹ́ òṣèré ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà àti olùfẹ́raǹ ọmọènìyàn.
Ó ka ilé-ìwé alákọ́bẹ̀rẹ̀ rẹ̀ ní Ìlú Èkó sááju kí ó tó lépa ilé-ẹ̀kọ́ girama rẹ̀ ní Queen of the Rosary College, ní ìlú Onitsha. Lẹ́hìn náà ló tẹ̀síwájú láti kẹ́ẹ̀kọ́ iṣẹ́ òṣèré ní Ilé-ẹ̀kọ́ gíga Obafẹ́mi Awólọ́wọ̀ .[1]Ó gba oyè aṣojú Àláfíà ti Àjọ Àgbáyé fún iṣẹ́ aláánú rẹ̀ ní gbogbo ilẹ̀ Adúnláwọ̀.[2]
Ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òṣèré rẹ̀ ṣíṣe ní ọdún 1980 ṣùgbọ́n ó di gbajúmọ̀ nígbàtí ó kópa nínu eré kan tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ "mirror in the Sun". Òun ni ọmọ Nàìjíríà àkọ́kọ́ láti gba àmì ẹ̀yẹ fún ti òṣèré lóbìnrin tó dára jùlọ níbi ayẹyẹ àjọ̀dún fíìmù ti ọdún 1982 tí FESPACO ṣe agbátẹrù rẹ̀ ní Burkina Faso.[3][4][5]
Chukwura jẹ́ ọmọbìnrin kan ṣoṣo nínu ìdílé eléyàn mẹ́rin tí a bí ní 24 Osù Keèje, ọdún 1964. Òun ni ìya Clarence Peters, enìkan tí n ṣe olùdarí fídíò orin . Ó jẹ́ ọmọ Ará ìlu Anambra .[6][7][8]
Ní ọdún 2016, Chukwura ṣe ìgbeyàwó fún ẹ̀kẹẹ̀ta pẹ̀lú Anthony Boyd, ó sì yípadà sí ìgbàgbọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ọkọ titun rẹ̀[9][10]