Bukky Ajayi | |
---|---|
Fáìlì:Bukky Ajayi.jpg Bukky Ajayi ninu ere | |
Ọjọ́ìbí | Oṣù Kejì 2, 1934 |
Aláìsí | July 6, 2016 Surulere, Ipinle Eko, Naijiria | (ọmọ ọdún 82)
Orílẹ̀-èdè | Naijiria |
Orúkọ míràn | Zainab Bukky Ajayi |
Iṣẹ́ | osere |
Ìgbà iṣẹ́ | 1966–2014 |
Zainab Bukky Àjàyí (2 Osù Keèjì 1934 – 6 Osù keèje 2016) jẹ́ òṣèré ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.[1]
Bukky Àjàyí ní a bí ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ṣùgbọ́n ó parí ẹ̀kọ́ gíga rẹ̀ ní orílẹ̀-èdè England, United Kingdom pẹ̀lú àtìlẹyìn síkọ́láshípù ìjọba àpapọ̀ kan. Ní ọdún 1965, ó kúrò ní England wá sí Nàìjíríà níbití iṣẹ́ rẹ̀ ti bẹ̀rẹ̀ gẹ́gẹ́ bi oníròyìn fún Nigerian Television Authority ní ọdún 1966.[2] Ó ṣe àkọ́kọ́ fiimu rẹ̀ nínu eré tẹlifíṣọ́nù "Village Headmaster" ní àwọn ọdún '70s ṣáájú kí ó tó lọ kópa nínuCheckmate, eré tẹlifíṣọ́nù Nàìjíríà kan tí wọ́n gbé síta ní àkókò ìgbẹ̀yìn àwọn ọdún 1980 sí ìbẹ̀rẹ̀ àwon ọdún 1990
Ní àkókò iṣẹ́ ìṣe eré rẹ̀, ó ṣe ìfihàn nínu ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn fiimu tó pẹ̀lú Critical Assignment, Diamond Ring, Witches làárín àwọn míràn. Ní ọdún 2016, àwọn ìlọ́wọ́sí rẹ̀ sí iṣẹ́ fiimu ti Nàìjíríà sokùn fa n tí wọ́n fi fun òun àti Sadiq Daba ní ẹ̀bun Industry Merit Award níbi ayẹyẹ 2016 Africa Magic Viewers Choice Awards.[3][4]
Fiimu | |||
---|---|---|---|
Ọdún | Fiimu | Ipa | Àfikún |
2013 | Mother of George | gẹ́gẹ́ bi Ma Ayọ̀ Balógun | dídarí eré látọwọ́ Andrew Dosunmu |
2009 | Bolode O'ku | — | — |
Òréré Layé | — | — | |
2008 | Amoye | — | — |
Iya Mi Tooto | — | — | |
2007 | A Brighter Sun | — | ó hàn níbi gbogbo àwọn ẹ̀yà |
Big Heart Treasure | — | ||
Fine Things | — | ||
Keep My Will | — | ||
2006 | Women of Faith | — | |
2005 | Bridge-Stone | — | |
Destiny's Challenge | — | — | |
Women's Cot | — | ó hàn níbi gbogbo àwọn ẹ̀yà | |
2004 | Indecent Girl | gẹ́gẹ́ bi Mrs. Orji | ó hàn níbi gbogbo àwọn ẹ̀yà |
Little Angel | — | — | |
Obirin Sowanu | — | — | |
Temi Ni, Ti E Ko | — | ó hàn níbi gbogbo àwọn ẹ̀yà | |
Worst Marriage | — | ||
2003 | The Kingmaker | — | — |
My Best Friend | — | — | |
2001 | Saving Alero | — | — |
Thunderbolt | — | — | |
2000 | Final Whistle | — | ó hàn níbi gbogbo àwọn ẹ̀yà |
Oduduwa | — | ||
1998 | Diamond Ring | — | — |
Witches | gẹ́gẹ́ bi ìya Desmond | — | |
1997 | Hostages | — | — |
1989 – 1991 | Checkmate | — | — |
— | Village Headmaster | — | — |
Àjàyí kú ní ìbùgbe rẹ̀ ní Surulere, Ìpínlẹ̀ Èkó ní ọjọ́ 6, oṣù keèje ọdún 2016 ní ọmọ ọdún 82.[5][6]